7 Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò.
8 Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si.
9 Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.
10 Oluwa wipe, nisisiyi li emi o dide, nisisiyi li emi o gbe ara mi soke.
11 Ẹ o loyun iyangbò, ẹ o si bi pòropóro; ẽmi nyin, bi iná, yio jẹ nyin run.
12 Awọn enia yio si dabi sisun ẽru, bi ẹgún ti a ké ni nwọn o jo ninu iná.
13 Ẹ gbọ́, ẹnyin ti o jìna rére, eyi ti mo ti ṣe; ati ẹnyin ti o sunmọ tosí, ẹ jẹwọ agbara mi.