10 Emi ha dá goke wá nisisiyi lẹhin Oluwa si ilẹ yi lati pa a run bi? Oluwa wi fun mi pe, Goke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.
11 Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.
12 Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?
13 Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria.
14 Bayi ni ọba na wi, pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori on kì o lè gbà nyin.
15 Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a ki o fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.
16 Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀;