16 Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀;
17 Titi emi o fi wá lati mu nyin lọ si ilẹ kan bi ilẹ ẹnyin tikala nyin, ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọ̀gba àjara.
18 Ẹ ṣọra ki Hesekiah ki o má pa nyin niyè dà wipe, Oluwa yio gbà wa, ọkan ninu òriṣa awọn orilẹ-ède ha gba ilẹ rẹ̀ lọwọ ọba Assiria ri bi?
19 Nibo li awọn òriṣa Hamati on Arfardi gbe wà? Nibo li awọn òriṣa Sefarfaimu wà? nwọn ha si ti gbà Samaria li ọwọ́ mi bi?
20 Tani ninu gbogbo oriṣa ilẹ wọnyi, ti o ti gbà ilẹ wọn kuro li ọwọ́ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro li ọwọ́ mi?
21 Ṣugbọn nwọn dakẹ, nwọn kò si da a lohùn ọ̀rọ kan: nitoriti aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a lohùn.
22 Nigbana ni Eliakimu, ọmọ Hilkia, ti iṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa, ọmọ Asafu akọwe iranti, wá sọdọ Hesekiah ti awọn ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.