6 Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ wi fun oluwa nyin, pe, Bayi ni Oluwa wi, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ ti iwọ ti gbọ́, nipa eyiti awọn iranṣẹ ọba Assiria ti fi sọ̀rọ buburu si mi.
7 Wò o, emi o fi ẽmi kan sinu rẹ̀, on o si gbọ́ iró kan, yio si pada si ilu on tikalarẹ̀; emi o si mu ki o ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.
8 Bẹ̃ni Rabṣake padà, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitori ti o ti gbọ́ pe o ti kuro ni Lakiṣi.
9 O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe,
10 Bayi ni ki ẹ wi fun Hesekiah ọba Juda, pe, Má jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle, ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọba Assiria lọwọ.
11 Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi?
12 Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari?