7 Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia.
8 Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai.
9 Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin!
10 Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀.
11 On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.
12 Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn?
13 Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ?