20 Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.
21 Mú ẹjọ nyin wá, ni Oluwa wi; mú ọràn dajudaju nyin jade wá, ni ọba Jakobu wi.
22 Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa.
23 Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i.
24 Kiyesi i, lati nkan asan ni nyin, iṣẹ nyin si jẹ asan: irira ni ẹniti o yàn nyin.
25 Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ.
26 Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin.