9 Ẹniti mo ti mu lati opin aiye wá, ti mo ti pè ọ lati ọdọ awọn olori enia ibẹ, ti mo si wi fun ọ pe, Iwọ ni iranṣẹ mi; mo ti yàn ọ, emi kò si ni ta ọ nù,
10 Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè.
11 Kiyesi i, gbogbo awọn ti o binu si ọ ni oju o tì, nwọn o si dãmu: nwọn o dabi asan; awọn ti o si mba ọ jà yio ṣegbe.
12 Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si.
13 Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ.
14 Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli.
15 Kiyesi i, emi ti ṣe ọ bi ohun-èlo ipakà mimú titun ti o ni ehín; iwọ o tẹ̀ awọn òke-nla, iwọ o si gún wọn kunná, iwọ o si sọ awọn oke kékèké di iyàngbo.