1 ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ.
2 Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.
3 Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ.
4 Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ.
5 Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá.
6 Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá.