1 ṢUGBỌN nisisiyi, gbọ́, iwọ Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ẹniti mo ti yàn:
2 Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn.
3 Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ.
4 Nwọn o si hù soke lãrin koriko, bi igi willo leti ipadò.
5 Ọkan yio wipe, ti Oluwa li emi, omiran yio si pe ara rẹ̀ nipa orukọ Jakobu; omiran yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọ pe, on ni ti Oluwa, yio si pe apele rẹ̀ nipa orukọ Israeli.