2 Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji.
3 Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli.
4 Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pè ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi.
5 Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi.
6 Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran.
7 Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.
8 Kán silẹ, ẹnyin ọrun, lati oke wá, ki ẹ si jẹ ki ofurufu rọ̀ ododo silẹ; jẹ ki ilẹ ki o là, ki o si mu igbala jade; si jẹ ki ododo ki o hù soke pẹlu rẹ̀; Emi Oluwa li o dá a.