10 Nitori ti iwọ ti gbẹkẹle ìwa buburu rẹ: iwọ ti wipe, Kò si ẹnikan ti o ri mi. Ọgbọ́n rẹ ati ìmọ rẹ, o ti mu ọ ṣinà; iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, ko si ẹlomiran lẹhin mi.
11 Nitorina ni ibi yio ṣe ba ọ; iwọ ki yio mọ̀ ibẹrẹ rẹ̀: ibi yio si ṣubu lù ọ; ti iwọ kì yio le mu kuro: idahoro yio deba ọ lojiji, iwọ kì yio si mọ̀.
12 Duro nisisiyi, ti iwọ ti iṣẹ afọṣẹ rẹ, ati ọpọlọpọ iṣẹ ajẹ́ rẹ, eyi ti o ti fi nṣe iṣẹ iṣe lati igba ewe rẹ wá; bi o ba ṣepe o lè jẹ erè fun ọ, bi o ba ṣe pe iwọ lè bori.
13 Arẹ̀ mu ọ nipa ọpọlọpọ ìgbimọ rẹ. Jẹ ki awọn awoye-ọrun, awọn awoye-irawọ, awọn afi-oṣupasọ-asọtẹlẹ, dide duro nisisiyi, ki nwọn si gbà ọ lọwọ nkan wọnyi ti yio ba ọ.
14 Kiye si i, nwọn o dabi akekù koriko: iná yio jo wọn: nwọn ki yio gba ara wọn lọwọ agbara ọwọ́ iná; ẹyin iná kan ki yio si lati yá, tabi iná lati joko niwaju rẹ̀.
15 Bayi ni awọn ti iwọ ti ba ṣiṣẹ yio jẹ fun ọ, awọn oniṣowo rẹ, lati ewe rẹ wá; nwọn o kiri lọ, olukuluku si ẹkùn rẹ̀; ko si ẹnikan ti yio gbà ọ.