12 Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin.
13 Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.
14 Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea.
15 Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde.
16 Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi.
17 Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ.
18 Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun.