7 Nisisiyi li a dá wọn, ki isi ṣe li atetekọṣe; ani ṣaju ọjọ na ti iwọ kò gbọ́ wọn; ki iwọ má ba wipe, Kiyesi i, emi mọ̀ wọn.
8 Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá.
9 Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro.
10 Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala.
11 Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.
12 Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin.
13 Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.