23 Awọn ọba yio jẹ baba olutọju rẹ, awọn ayaba wọn yio si jẹ iya olutọju rẹ; ni idojubolẹ ni nwọn o ma tẹriba fun ọ, nwọn o si lá ekuru ẹsẹ rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa; nitori oju kì yio tì awọn ti o ba duro dè mi.
24 A ha le gba ikogun lọwọ alagbara bi? tabi a le gbà awọn ondè lọwọ awọn ẹniti nwọn tọ́ fun?
25 Ṣugbọn bayi ni Oluwa wi, a o tilẹ̀ gbà awọn ondè kuro lọwọ awọn alagbara, a o si gbà ikogun lọwọ awọn ẹni-ẹ̀ru; nitori ẹniti o mba ọ jà li emi o ba jà, emi o si gbà awọn ọmọ rẹ là.
26 Awọn ti o ni ọ lara li emi o fi ẹran ara wọn bọ́, nwọn o mu ẹjẹ ara wọn li amuyo bi ọti-waini didùn: gbogbo ẹran-ara yio si mọ̀ pe, Emi Oluwa ni Olugbala ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara ti Jakobu.