12 Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ.
14 Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀.
15 Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ.
16 Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo.
17 Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ.
18 Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ.