17 Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ.
18 Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ.
19 Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.
20 Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò!
21 Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn!
22 Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile:
23 Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀.