1 BAYI ni Oluwa wi, Nibo ni iwe ikọsilẹ iyá nyin gbe wà, ẹniti mo ti kọ̀ silẹ? tabi tani ninu awọn onigbese mi ti mo ti tà nyin fun? Kiyesi i, nitori aiṣedẽde nyin li ẹnyin ti tà ara nyin, ati nitori irekọja nyin li a ṣe kọ̀ iyá nyin silẹ.
2 Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ.
3 Mo fi ohun dúdu wọ̀ awọn ọrun, mo si fi aṣọ ọfọ̀ ṣe ibora wọn.
4 Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ.