6 Ẹ wá Oluwa nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e nigbati o wà nitosí.
7 Jẹ ki enia buburu kọ̀ ọ̀na rẹ̀ silẹ, ki ẹ̀lẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ.
8 Nitori èro mi kì iṣe èro nyin, bẹ̃ni ọ̀na nyin kì iṣe ọ̀na mi, li Oluwa wi.
9 Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹ̃ni ọ̀na mi ga ju ọ̀na nyin lọ, ati èro mi ju èro nyin lọ.
10 Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun:
11 Bẹ̃ni ọ̀rọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán a.
12 Nitori ayọ̀ li ẹ o fi jade, alafia li a o fi tọ́ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ́ yio si ṣapẹ́.