1 KIYESI i, ọwọ́ Oluwa kò kuru lati gbàni, bẹ̃ni eti rẹ̀ kò wuwo ti kì yio fi gbọ́.
2 Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́.
3 Nitori ọwọ́ nyin di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ, ati ika nyin fun aiṣedede, ète nyin nsọ eke, ahọn nyin nsọ ibi jade.
4 Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.
5 Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.