13 Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá.
14 A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile.
15 Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si.
16 O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró.
17 O si gbe ododo wọ̀ bi awo-aiya, o si fi aṣibori irin igbala dé ara rẹ̀ lori: o wọ̀ ẹwù igbẹsan li aṣọ, a si fi itara wọ̀ ọ bi agbada.
18 Gẹgẹ bi ere iṣe wọn, bẹ̃ gẹgẹ ni yio san a fun wọn, irunú fun awọn ọta rẹ̀, igbẹsan fun awọn ọta rẹ̀; fun awọn erekuṣu yio san ẹsan.
19 Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i.