18 Gẹgẹ bi ere iṣe wọn, bẹ̃ gẹgẹ ni yio san a fun wọn, irunú fun awọn ọta rẹ̀, igbẹsan fun awọn ọta rẹ̀; fun awọn erekuṣu yio san ẹsan.
19 Nwọn o si bẹ̀ru orukọ Oluwa lati ìwọ-õrùn wá, ati ogo rẹ̀ lati ilà-õrun wá. Nigbati ọta yio de bi kikún omi, Ẹmi Oluwa yio gbe ọpágun soke si i.
20 Olurapada yio si wá si Sioni, ati sọdọ awọn ti o yipada kuro ninu irekọja ni Jakobu, ni Oluwa wi.
21 Niti emi, eyi ni majẹmu mi pẹlu wọn, ni Oluwa wi; Ẹmi mi ti o wà lara rẹ̀, ati ọ̀rọ mi ti mo fi si ẹnu rẹ, kì yio kuro li ẹnu rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ rẹ, tabi kuro lẹnu iru-ọmọ ọmọ rẹ, ni Oluwa wi, lati isisiyi lọ ati lailai.