10 Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ.
11 Nitori na awọn ẹnu-bodè rẹ yio ṣi silẹ nigbagbogbo; a kì yio se wọn lọsan tabi loru, ki a le mu ọla awọn Keferi wá sọdọ rẹ, ki a ba si mu awọn ọba wọn wá.
12 Nitori orilẹ-ède, tabi ilẹ ọba ti kì yio sin ọ, yio ṣegbe; orilẹ-ède wọnni li a o sọ dahoro raurau.
13 Ogo Lebanoni yio wá sọdọ rẹ, igi firi, igi pine, pẹlu igi boksi, lati ṣe ibi mimọ́ mi li ọṣọ; emi o ṣe ibi ẹsẹ mi logo.
14 Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli.
15 Ni bi a ti kọ̀ ọ silẹ, ti a si ti korira rẹ, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja lãrin rẹ, emi o sọ ọ di ogo aiyeraiye, ayọ̀ iran-de-iran ọ̀pọlọpọ.
16 Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu.