2 Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn Oluwa yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rẹ̀ lara rẹ.
3 Awọn keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ.
4 Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ.
5 Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.
6 Ọ̀pọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati Ṣeba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn Oluwa hàn sode.
7 A o ṣà gbogbo ọwọ́-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo.
8 Tani wọnyi ti nfò bi awọsanma, ati bi awọn ẹiyẹle si ojule wọn?