15 Wò ilẹ lati ọrun wá, ki o si kiyesi lati ibugbe ìwa mimọ́ rẹ ati ogo rẹ wá: nibo ni itara rẹ ati agbara rẹ, ọ̀pọlọpọ iyanu rẹ, ati ãnu rẹ sọdọ mi gbe wà? a ha da wọn duro bi?
16 Laiṣiyemeji iwọ ni baba wa, bi Abrahamu tilẹ ṣe alaimọ̀ wa, ti Israeli kò si jẹwọ wa: iwọ Oluwa, ni baba wa, Olurapada wa; lati aiyeraiye ni orukọ rẹ.
17 Oluwa, nitori kili o ṣe mu wa ṣina kuro li ọ̀na rẹ, ti o si sọ ọkàn wa di lile kuro ninu ẹ̀ru rẹ? Yipada nitori awọn iranṣẹ rẹ, awọn ẹya ilẹ ini rẹ.
18 Awọn enia mimọ́ rẹ ti ni i, ni igba diẹ: awọn ọta wa ti tẹ̀ ibi mimọ́ rẹ mọlẹ.
19 Tirẹ li awa: lati lailai iwọ kò jọba lori wọn, a kò pè orukọ rẹ mọ wọn.