2 Nitori kini aṣọ rẹ fi pọ́n, ti aṣọ rẹ wọnni fi dabi ẹniti ntẹ̀ ohun-èlo ifunti waini?
3 Emi nikan ti tẹ̀ ohun-elò ifunti waini; ati ninu awọn enia, ẹnikan kò pẹlu mi: nitori emi tẹ̀ wọn ninu ibinu mi, mo si tẹ̀ wọn mọlẹ ninu irunú mi; ẹ̀jẹ wọn si ta si aṣọ mi, mo si ṣe gbogbo ẹ̀wu mi ni abawọ́n.
4 Nitori ọjọ ẹsan mbẹ li aiya mi, ọdun awọn ẹni-irapada mi ti de.
5 Mo si wò, kò si si oluranlọwọ; ẹnu si yà mi pe kò si olugbéro; nitorina apa ti emi tikalami mu igbala wá sọdọ mi; ati irunú mi, on li o gbe mi ro.
6 Emi si tẹ̀ awọn enia mọlẹ ninu ibinu mi, mo si mu wọn mu yó ninu irunú mi, mo si mu ipa wọn sọkalẹ si ilẹ.
7 Emi o sọ ti iṣeun ifẹ Oluwa, iyìn Oluwa gẹgẹ bi gbogbo eyiti Oluwa ti fi fun wa, ati ti ore nla si ile Israeli, ti o ti fi fun wọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀, ati gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ iṣeun ifẹ rẹ̀.
8 On si wipe, Lõtọ enia mi ni nwọn, awọn ọmọ ti kì iṣeke: on si di Olugbala wọn.