10 Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri.
11 Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni.
12 Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
13 Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:
14 Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.
15 Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:
16 Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.