17 Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.
18 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀.
19 Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.
20 Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu.
21 Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn.
22 Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn.
23 Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn.