3 Awọn enia ti o nṣọ́ mi ni inu nigbagbogbo kàn mi loju; ti nrubọ ninu agbàla, ti nwọn si nfi turari jona lori pẹpẹ briki.
4 Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn;
5 Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni.
6 Kiyesi i, a ti kọwe rẹ̀ niwaju mi: emi kì o dakẹ, ṣugbọn emi o gbẹ̀san, ani ẹ̀san si aiya wọn,
7 Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn.
8 Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run.
9 Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ.