8 Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run.
9 Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ.
10 Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri.
11 Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni.
12 Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
13 Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin:
14 Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.