1 BAYI ni Oluwa wi, pe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si ni apoti itisẹ̀ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ́ fun mi gbé wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà?
2 Nitori gbogbo nkan wọnni li ọwọ́ mi sa ti ṣe, gbogbo nkan wọnni si ti wà, li Oluwa wi: ṣugbọn eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oniròbinujẹ ọkàn, ti o si nwarìri si ọ̀rọ mi.
3 Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn.
4 Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn, emi o si mu eyi ti nwọn bẹ̀ru wá sara wọn, nitori nigbati mo pè, kò si ẹnikan ti o dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, nwọn kò gbọ́: ṣugbọn nwọn ṣe buburu niwaju mi, nwọn si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.
6 Ohùn ariwo lati inu ilu wá, ohùn lati inu tempili wá, ohùn Oluwa ti nsan ẹ̀san fun awọn ọta rẹ̀.
7 Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan.