3 Ẹniti o pa akọ-malu, o dabi ẹnipe o pa enia; ẹniti o fi ọdọ-agutan rubọ, a dabi ẹnipe o bẹ́ ajá lọrùn; ẹniti o rubọ ọrẹ, bi ẹnipe o fi ẹ̀jẹ ẹlẹdẹ̀ rubọ; ẹniti o fi turari jona, bi ẹniti o sure fun òriṣa. Nitotọ, nwọn ti yàn ọ̀na ara wọn, inu wọn si dùn si ohun iríra wọn.
4 Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn, emi o si mu eyi ti nwọn bẹ̀ru wá sara wọn, nitori nigbati mo pè, kò si ẹnikan ti o dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, nwọn kò gbọ́: ṣugbọn nwọn ṣe buburu niwaju mi, nwọn si yàn eyiti inu mi kò dùn si.
5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.
6 Ohùn ariwo lati inu ilu wá, ohùn lati inu tempili wá, ohùn Oluwa ti nsan ẹ̀san fun awọn ọta rẹ̀.
7 Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan.
8 Tali o ti igbọ́ iru eyi ri? tali o ti iri irú eyi ri? Ilẹ le hù nkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède ni ọjọ́ kan nã? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹ̃li o bi awọn ọmọ rẹ̀.
9 Emi o ha mu wá si irọbi, ki nmá si mu ki o bi? li Oluwa wi: emi o ha mu ni bi, ki nsi sé inu? li Ọlọrun rẹ wi.