5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.
6 Ohùn ariwo lati inu ilu wá, ohùn lati inu tempili wá, ohùn Oluwa ti nsan ẹ̀san fun awọn ọta rẹ̀.
7 Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan.
8 Tali o ti igbọ́ iru eyi ri? tali o ti iri irú eyi ri? Ilẹ le hù nkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède ni ọjọ́ kan nã? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹ̃li o bi awọn ọmọ rẹ̀.
9 Emi o ha mu wá si irọbi, ki nmá si mu ki o bi? li Oluwa wi: emi o ha mu ni bi, ki nsi sé inu? li Ọlọrun rẹ wi.
10 Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u.
11 Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀.