3 Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi.
4 Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.
5 Oluwa si tun wi fun mi pe,
6 Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.
7 Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.
8 Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.
9 Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.