5 Oluwa si tun wi fun mi pe,
6 Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.
7 Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.
8 Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.
9 Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.
10 Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.
11 Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,