1 Sámúẹ́lì 10:1-5 BMY

1 Sámúẹ́lì sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olóri í lórí ohun ìní rẹ̀?

2 Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rákélì ní Sélísà, ní agbégbé Bẹ́ńjámínì. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsìn yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń damú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípà ọmọ mi?” ’

3 “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi Tábórì ńlá. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, iṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹtà yóò mú ìgò wáìnì.

4 Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ ọ wọn.

5 “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú líárì, támborí àti fèrè àti gìta níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àṣọtẹ́lẹ̀.