1 Sámúẹ́lì 23 BMY

Dáfídì Gbà Kéílà Lọ́wọ́ Àwọn Fílístínì.

1 Wọ́n sì wí fún Dáfídì pé, “Ṣá wò ó, àwọn ará Fílístínì ń bá ará Kéílà jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.”

2 Dáfídì sì béèré lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Fílístínì wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Fílístínì kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.”

3 Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhín yìí ní Júdà; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Kéílà láti fi ojú ko ogun àwọn ara Fílístínì?”

4 Dáfídì sì tún béèrè lọ́dọ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Fílístínì náà lé ọ lọ́wọ́.”

5 Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Kéílà, wọ́n sì bá àwọn ará Fílístínì jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dáfídì sì gba àwọn ará Kéílà sílẹ̀.

6 Ó sì ṣe, nígbà tí Ábíátarì ọmọ Áhímélékì fi sá tọ Dáfídì lọ ní Kéílà, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú éfódù kan lọ́wọ́ rẹ̀.

7 A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí Kéílà. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.”

8 Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

9 Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, “Mú éfódù náà wá níhínìnyìí!”

10 Dáfídì sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.

11 Àwọn àgbà ìlú Kéílà yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Ṣọ́ọ̀lù yóò hà sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

12 Dáfídì sì wí pé, “Àwọn àgbà ilú Kéílà yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Ṣọ́ọ̀lù lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

13 Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìdé, wọ́n lọ kúrò ní Kéílà, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà; kò sì lọ sí Kéílà mọ́.”

14 Dáfídì sì ń gbé ní ihà, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè-ńlá kan ní ihà Sífì. Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá a lójóojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

Àwọn Ará Sífì Dalẹ̀ Dáfídì.

15 Dáfídì sì ríi pé, Ṣọ́ọ̀lù ti jáde láti wá ẹ̀mi òun kiri: Dáfídì sì wà ní ihà Sífì nínú igbó kan.

16 Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì dìde, ó sì tọ Dáfídì lọ nínú igbó náà, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run.

17 Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Ṣọ́ọ̀lù baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

18 Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa; Dáfídì sì jókòó nínú igbó náà. Jónátanì sì lọ sí ilé rẹ̀.

19 Àwọn ará Sífì sì gòkè tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dáfídì ti fi ara rẹ̀ pamọ̀ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Hórésì, ní òkè Hákílà, tí ó wà níhà gúsù ti Jésímọ́nì.

20 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.”

21 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi.

22 Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé. Ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ.

23 Ẹ sì wo, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Júdà!”

24 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì: ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì.

25 Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dáfídì: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní ihà ti Máónì. Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́, ó sì lépa Dáfídì ní ihà Máónì.

26 Ṣọ́ọ̀lù sì ń rin apákan òkè kan, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apákejì òkè náà. Dáfídì sì yára láti sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù; nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn.

27 Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Fílístínì ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.”

28 Ṣọ́ọ̀lù sì padà kúrò ní lilépa Dáfídì, ó sì lọ pàdé àwọn Fílístínì nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní òkúta ìpínyà.

29 Dáfídì sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní Éńgédì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31