1 Sámúẹ́lì 6 BMY

Àpótí Ẹ̀rí Olúwa Padà Sí Ísírẹ́lì

1 Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Fílístínì fún oṣù méje,

2 àwọn ará Fílístínì pe àwọn àlùfáà, àti àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí àyè rẹ̀.”

3 Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Olúwa ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”

4 Àwọn ará Fílístínì béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”Wọ́n dáhùn, “Góòlù oníkókó márùn ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn ún, gẹ́gẹ́ bí iye awọn aláṣẹ Fílístínì, nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.

5 Mọ àwòrán àrùn oníkókó àti ti eku èlírí yin tí ó ń ba orílẹ̀ èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.

6 Kí ni ó dé tí ẹ fi ń ṣé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Éjíbítì àti Fáráò ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣe wọn kò rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?

7 “Nísinsìnyìí ẹ pèse kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fí ọmú fun ọmọ, èyí tí a kò tí ì fi ru ẹrù rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so.

8 Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ,

9 ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Bẹti-Sémésì. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọ lù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni”

10 Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dèé ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé.

11 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán àrùn oníkókó wà níbẹ̀.

12 Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Béti-Ṣémésì, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Fílístínì tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Bẹti-Sémésì.

13 Nísinsìn yìí, àwọn ará Bẹti-Sémésì ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀.

14 Kẹ̀kẹ̀ ẹrù wá sí pápá Jóṣúà ti Bẹti-Sémésì, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rúbọ sísun sí Olúwa.

15 Àwọn ará Léfì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìṣàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Bẹti-Sémésì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa.

16 Àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ékírónì.

17 Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Fílístínì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ásídódù, ọ̀kan ti Gásà, ọ̀kan ti Ásíkélónì, ọ̀kan ti Gátì, ọ̀kan ti Ékírónì.

18 Góòlù eku-ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún ti wá, ìlú olodi pẹ̀lú ìlétò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Jóṣúà ará Bẹti-Sémésì.

19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ lu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Bẹti-Sémésì, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà.

20 Àwọn ọkùnrin ará Bẹti-Sémésì béèrè pé, “Ta ni ó le è dúró ní iwájú Olúwa Ọlọ́run mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò gbà gòkè lọ láti ibí yìí?”

21 Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati Jéárímì wí pé, “àwọn Fílístínì ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31