1 Sámúẹ́lì 1 BMY

Ìbí Sámúẹ́lì

1 Ọkùnrin kan wà, láti Rámátaímù-Sófímù, láti ìlú olókè Éfúráímù, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikánà, ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfù, ará Éfírátà.

2 Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hánà àti Pẹ̀nínà: Pẹ̀nínà ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò ní.

3 Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa alágbára jùlọ ní Ṣílò, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.

4 Nígbàkígbà tí ó bá kan Elikánà láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Pẹ̀nínà àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin.

5 Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hánà nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú.

6 Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín in níràn láti lè mú kí ó bínú.

7 Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hánà bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín-in níràn títí tí yóò fi máa sunkún tí kò sì ní lè jẹun.

8 Elikánà ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hánà èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”

9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣílò, Hánà dìde wá ṣíwájú Olúwa. Nígbà náà, Élì àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó.

10 Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hánà sunkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

11 Ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ wí pé, “Olúwa alágbára jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́-bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí iwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”

12 Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Élì sì kíyèsí ẹnu rẹ̀.

13 Hánà ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Élì rò wí pé ó ti mu ọtí yó.

14 Ó sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”

15 Hánà dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.

16 Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”

17 Élì dáhùn pé, “Má a lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

18 Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọbinrin náà bá tirẹ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.

19 Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà: Elikánà si mọ aya rẹ̀: Olúwa sì rántì rẹ̀.

20 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, pé, “Nítorí tí mo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”

A ya Sámúẹ́lì sí mímọ́ fún Olúwa.

21 Ọkùnrin náà Elikánà, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rúbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

22 Ṣùgbọ́n Hánà kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”

23 Elikánà ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa ṣáà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.

24 Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun éfà kan, àti ìgò ọti-wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣílò: ọmọ náà ṣì wà ní ọmọdé.

25 Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Élì wá.

26 Hánà sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láàyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa.

27 Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi.

28 Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fí i fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa nibẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31