1 Sámúẹ́lì 21 BMY

Áhímélékì Àlùfáà Fún Dáfídì Ni Àkàrà Mímọ́ Jẹ.

1 Dáfídì sì wá sí Nóbù sọ́dọ̀ Áhímélékì àlùfáà, Áhímélékì sì bẹ̀rù láti pàdé Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Èé ha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ.”

2 Dáfídì sì wí fún Áhímélékì àlùfáà pé, “Ọbá pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.

3 Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn ún tabi ohunkohun tí o bá rí.”

4 Àlùfáà náà sí dá Dáfídì lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́; Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pá ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”

5 Dáfídì sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin nígbàkùúgbà ti mo bá jáde ìrìn-àjò, gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, pàápàá nígbà ìrìn-àjò kékèké; kò há ní mọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ lónìí bí?”

6 Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fí àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn nibẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.

7 Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dá dúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóégì, ará Édómù olórí nínú àwọn darandaran Ṣọ́ọ̀lù.

Dáfídì Gbá Idà Góláyátì Lọ́wọ́ Àlùfáà Náà.

8 Dáfídì sì tún wí fún Áhímélékì pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”

9 Àlùfáà náà sì wí pé, “Idàn Gòláyátì ará Fílístínì tí ó pa ní àfonífojì Élà ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn Éródù; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.”Dáfídì sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”

A Mú Dáfídì Wa Sọ́dọ̀ Ákísì, Ọba Gátì.

10 Dáfídì sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Ṣọ́ọ̀lù, ó sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì, ọba Gátì.

11 Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sì wí fún un pé, “Èyí há kọ́ ní Dáfídì ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé,“ ‘Ṣọ́ọ̀lù pá ẹgbẹ̀rún tírẹ.Dáfídì sì pa ẹgbàarún tirẹ̀’?”

12 Dáfídì sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ákíṣì ọba Gátì gidigidi.

13 Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irungbọ̀n rẹ̀.

14 Nígbà náà ni Ákíṣì wí fún àwọn ìrańṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá.

15 Mo há ni un fi aṣiwèrè ṣe? Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá lati hú ìwà aṣiwèrè níwájú mi? Eléyìí yóò há wọ inú ilé mi?”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31