1 Sámúẹ́lì 25 BMY

Nabali Kọ Lati Ran Dáfídì Lọ́wọ́.

1 Sámúẹ́lì sì kú; gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sunkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama.Dáfídì sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Páránì.

2 Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Máónì, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Kámẹ́lì; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámẹ́lì.

3 Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nábálì, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Ábígáílì; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kálẹ́bù ni òun jẹ́.

4 Dáfídì sì gbọ́ ní ihà pé Nábálì ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.

5 Dáfídì sì rán ọmọkùnrin mẹwàá, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Kámẹ́lì, kí ẹ sì tọ Nábálì lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.

6 Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!

7 “ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ̀run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùsọ́ àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pà wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Kámẹ́lì.

8 Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àṣè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣe rẹ, àti fún Dáfídì ọmọ rẹ.’ ”

9 Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nábálì gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dáfídì, wọ́n sì sinmi.

10 Nábálì sì dá àwọn ìránṣẹ Dáfídì lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dáfídì? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jésè? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iránṣe ni ń bẹ ni isinsinyìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.

11 Ǹjẹ́ ki èmi o mú òunjẹ́ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pá fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi si fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”

12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì pada, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

13 Dáfídì sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idá rẹ́ mọ́ idi,” Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ́ rẹ́ mọ̀ ìdí; àti Dáfídì pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dáfídì lẹ́yin; igba si jókòó nibi ẹrù.

14 Ọkan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Ábígáílì aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dáfídì rán oníṣẹ́ láti ihà wá láti ki olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn.

15 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà ṣe oore fún wa gidigidi, wọn kò ṣe wá ní ibi kan, ohunkóhun kò nù ni ọwọ́ wa ni gbogbo ọjọ́ ti àwa bá wọn rìn nígbà ti àwa ń bẹ lóko.

16 Odi ni wọ́n sáà jásí fún wa lọ́sànán, àti lóru, ni gbogbo ọjọ́ ti a fi bá wọn gbé, tí a n bojútó àwọn àgùntàn.

17 Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Bélíálì tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”

18 Ábígáílì sì yára, ó sì mú igba ìṣù àkàrà àti ìgò-ọtí wáìnì méjì, àti àgùntàn márùn-ún, ti a ti ṣè, àti oṣuwọn àgbàdo yíyan márùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún ìdì àjàrà, àti igba àkàrà èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

19 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùrin rẹ̀ pé, “Má a lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” Ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nábálì baálé rẹ̀.

20 Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn.

21 Dáfídì sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyi tí i ṣe ti eléyìí ní ihà, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni o sì fi ibi san ire fún mi yìí.

22 Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀ta Dáfídì, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.”

23 Ábígáílì sì rí Dáfídì, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.

24 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

25 Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Bélíálì yìí sí, àní Nábálì: nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí: Nábálì ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.

26 “Ǹjẹ́ Olúwa mi, bi Olúwa ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì.

27 Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

28 Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ní: nítorí Olúwa yóò fi ìdí ìjọba olúwa mi múlẹ̀, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láàyè.

29 Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi mú láàyè lọdọ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀ta rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

30 Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì.

31 Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gbẹ̀san fún ara rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

32 Dáfídì sì wí fún Ábígáílì pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.

33 Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi.

34 Nítòòtọ́ ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”

35 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.”

36 Ábígáílì sì tọ Nábálì wá, sì wò ó, òun sì ṣe àṣè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àsè ọba: inú Nábálì sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀

37 Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nábálì, obìnrin rẹ̀ si ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta.

38 Ó sì ṣe lẹ́yin ìwọ̀n ijọ mẹ́wàá, Olúwa lu Nábálì, ó sì kú.

39 Dáfídì sì gbọ́ pé Nábálì kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbéjà gígàn mi láti ọwọ́ Nábálì wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ikà Nábálì sí orí òun tìkárarẹ̀.”Dáfídì sì ránṣẹ́, ó sì ba Ábígáílì sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.

40 Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì lọ sọ́dọ̀ Ábígáílì ni Kamẹ́lì, wọn sì sọ fún un pé, “Dáfídì rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.”

41 Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”

42 Ábígáílì sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn iránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùnún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn; oun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, o sì wá di aya rẹ̀.

43 Dáfídì sì mú Áhínóámù ará Jésírẹ́lì; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀.

44 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti fi Míkálì ọmọ rẹ̀ obìnrin aya Dáfídì, fún Fátíélì ọmọ Láìsi tí i ṣe ara Gálímù.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31