1 Sámúẹ́lì 28 BMY

Ṣọ́ọ̀lù Tọ Abókúsọ̀rọ̀ Lọ.

1 Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Fílístínì sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Ísírẹ́lì jà. Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, “Mọ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ.”

2 Dáfídì sì wí fún Ákíṣì, pé, “Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ rẹ lè ṣe.”Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, “Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́.”

3 Sámúẹ́lì sì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rámà ní ìlú rẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.

4 Àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣúnémù: Ṣọ́ọ̀lù sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gílíbóà.

5 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì rí ogun àwọn Fílístínì náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

6 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Úrímù tàbí nípa àwọn wòlíì.

7 Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mi abókúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Ẹ́ńdórì tí ó ní ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀.”

8 Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

9 Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé “Wò ó, ìwọ sáà mọ ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ṣe, bí òun ti gé àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èé ha ṣe tí ìwọ dẹ́kùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”

10 Ṣọ́ọ̀lù sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”

11 Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”Òun sì wí pé, “Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi.”

12 Nígbà tí obìnrin náà sì rí Sámúẹ́lì, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ni ìwọ jẹ́.”

13 Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?”Obìnrin náà sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi rí ẹ̀mí kan tí ó ti ilẹ̀ wá.”

14 Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.”Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.”Ṣọ́ọ̀lù sì mọ̀ pé, Sámúẹ́lì ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

15 Sámúẹ́lì sì i wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Fílístínì ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”

16 Sámúẹ́lì sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.

17 Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dáfídì.

18 Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Ámálékì nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.

19 Olúwa yóò sì fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́: ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”

20 Lojúkan náà ni Ṣọ́ọ̀lù ṣubú lulẹ̀ gbalaja ní bí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà t'ọ̀sán t'òru.

21 Obìnrin náà sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mi mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi.

22 Ǹjẹ́, nísinsìnyìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ ṣíwájú rẹ̀; sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà.”

23 Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé, “Èmi kì yóò jẹun.”Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rọ̀ ọ́. Ó sì dide kúrò ni ilẹ̀, ó sì jókòó lorí àkéte.

24 Obìnrin náà sì ni ẹgbọrọ màlúù kan ti ó sańra ni ilé, ó sì yára, ó pa á, ó sì mú ìyẹ̀fún, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà àìwú.

25 Ó sì mú un wá ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù, àti ṣíwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀; wọ́n sì jẹun. Wọ́n sì dìde, wọ́n lọ ní òru náà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31