1 Sámúẹ́lì 30 BMY

Dáfídì Pa Gbogbo Àwọn Ámálékì.

1 Ó sì ṣe nigbà ti Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bọ̀ sí Síkílágì ní ọjọ́ kẹta, àwọn ará Ámálékì sì ti kọlu Néséfà, àti Síkílágì, wọ́n sì ti kùn ún ní iná.

2 Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbékùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ.

3 Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú, sì wò ó, a ti kun ún ni iná; àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbinrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ.

4 Dáfídì àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sunkún.

5 A sì kó àwọn aya Dáfídì méjèèjì nígbèkùn lọ, Áhínóámù ará Jésírẹ́lì àti Ábígáílì aya Nábálì ará Kámélì.

6 Dáfídì sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítori ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dáfídì mu ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

7 Dáfídì sì wí fún Ábíátárì àlùfáà, ọmọ Áhímélékì pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú éfódù fún mi wá níhín-ín yìí. Ábíátarì sì mú éfódù náà wá fún Dáfídì.

8 Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?”Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”

9 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti ẹgbẹ̀tà ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi ọ̀dọ̀ Bésórì, apákan sì dúró.

10 Ṣùgbọ́n Dáfídì àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, ti wọn kò lè kọjá odò Bésórì sì dúró lẹ́yìn.

11 Wọ́n sì rí ara Éjíbítì kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dáfídì wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu.

12 Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ṣírí àjàrà gbígbẹ́ méjì: nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì ṣojí: nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ijọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru.

13 Dáfídì sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?”Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Éjíbítì ni èmi, ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Ámálékì. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ijọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn.

14 Àwa sì gbé ogun lọ síhà Gúúsù tí ara Kérítì, àti sí ìhà ti Júdà, àti sí ìhà Gúúsù ti Kélẹ́bù; àwa sì kun Síkílágì ní iná.”

15 Dáfídì sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?”Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.”

16 Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Fílístínì wá, àti láti ilẹ̀ Júdà.

17 Dáfídì sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ijọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irínwó ọmọkùnrin tí wọ́n gun ràkúnmí tí wọ́n sì sá.

18 Dáfídì sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Ámálékì ti kó: Dáfídì sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì.

19 Kò sì sí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó: Dáfídì sì gba gbogbo wọn.

20 Dáfídì sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáàjú àwọn ohun mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dáfídì.”

Dáfídì sí pín ìkógun náà.

21 Dáfídì sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, ti wọn kò lè tọ́ Dáfídì lẹ́yin mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni odò Bésórì: wọ́n sì lọ pàdé Dáfídì, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dáfídì sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn.

22 Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Bélíálì nínú àwọn tí o bá Dáfídì lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”

23 Dáfídì sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́-ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́.

24 Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọran yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.”

25 Lati ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Ísírẹlì títí di òní yìí.

26 Dáfídì sì padà sí Síkílágì, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbà Júdà, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀ta Olúwa wa.”

27 Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Bẹ́tẹ́lì àti sí àwọn tí ó wà ní Gúúsù tí Rámótì, àti sí àwọn tí ó wà ní Játírì.

28 Àti sí àwọn tí ó wà ní Áróérì, àti sí àwọn tí ó wà ní Sífímótì, àti sí àwọn tí ó wà ni Ésítémóà.

29 Àti si àwọn tí ó wà ni Rákélì, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jérámélì, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Kéni.

30 Àti sí àwọn tí ó wà ni Hórímà, àti àwọn ti ó wà ní Kórásánì, àti sí àwọn tí ó wà ni Átakì.

31 Àti àwọn tí ó wà ni Hébírónì, àti sí gbogbo àwọn ilú ti Dáfídì tìkárarẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìnká.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31