1 Sámúẹ́lì 9 BMY

Sámúẹ́lì Fi Òróró Yan Ṣọ́ọ̀lù

1 Ará Bẹ́ńjámínì kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíṣì, ọmọ Ábíélì, ọmọ Sésórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà ti Bẹ́ńjámínì.

2 Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Ṣọ́ọ̀lù, ọ̀dọ̀mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàárin gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì—láti èjìka rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga jú gbogbo àwọn ènìyàn tó kù lọ.

3 Nísinsìn yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù sì sọnù. Nígbà náà, Kíṣì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”

4 Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrin àwọn ìlú olókè Éfúráímù, ó sì kọja ní àyíká ilẹ̀ Sálísà, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Sálímù, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Bẹ́ńjámínì, wọn kò sì rí wọn.

5 Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Ṣúfù, Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”

6 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ ṣíbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a ó ò gbà.”

7 Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”

8 Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin Ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.”

9 (Tẹ́lẹ̀ ní Ísírẹ́lì tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, Jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀ ìsinsìn yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).

10 Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára “Jẹ́ kí a lọ” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.

11 Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?”

12 “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsìn yìí, ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.

13 Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbúdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsìn yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

14 Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Sámúẹ́lì, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15 Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé,

16 “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17 Nígbà tí Sámúẹ́lì fojú rí Ṣọ́ọ̀lù, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18 Ṣọ́ọ̀lù sì súnmọ́ Sámúẹ́lì ní ẹnu ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

19 Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.

20 Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dàamú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Ísírẹ́lì wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21 Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há à ṣe ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Kékeré nínú ẹ̀yá Ísírẹ́lì: Ìdílé mi kò há rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹyà Bẹ́ńjámínì? Èésì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

22 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n.

23 Sámúẹ́lì sọ fún aláṣè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

24 Alásè náà sì gbé ẹṣẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Ṣọ́ọ̀lù sì jẹun pẹ̀lú Sámúẹ́lì ní ọjọ́ náà.

25 Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Sámúẹ́lì sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀.

26 Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́jú, ó pe Ṣọ́ọ̀lù sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù múra tán òun àti Sámúẹ́lì jọ jáde lọ síta.

27 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ̀ẹ́, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ Ọlọ́run fún ọ.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31