1 Sámúẹ́lì 11 BMY

Ṣọ́ọ̀lù Gba Ìlú Jábésì Sílẹ̀

1 Náhásì ará Ámónì gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi-Gílíádì, gbogbo ọkùnrin Jábésì sì wí fún Néhásì pé, “Bá wa ṣe ìpinnú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”

2 Ṣùgbọ́n Náhásì ará Ámónì sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi ó ò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọtún yín kúró, èmi o si fi yín se ẹlẹ́yà lójú gbogbo Ísírẹ́lì.”

3 Àwọn àgbà Jábésì sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”

4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gíbíà tí ó jẹ́ ìlú Ṣọ́ọ̀lù, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún.

5 Nígbà náà gan an ni Ṣọ́ọ̀lù padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sunkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábésì.

6 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.

7 Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyọyọ sí gbogbo Ísírẹ́lì nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Ṣọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.

8 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì kó wọn jọ ní Bésékì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún. (300,000) àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún (30,000).

9 Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi-Gílíádì pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jábésì, inú wọn sì dùn.

10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Ámónì pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”

11 Ní ọjọ́ kejì Ṣọ́ọ̀lù pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ámónì ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóju ọjọ́. Àwọn tó kù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.

Wọ́n Fi Ẹṣẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù Múlẹ̀ Bí Ọba

12 Àwọn ènìyàn sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Ṣọ́ọ̀lù yóò ha jọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”

13 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa gba Ísírẹ́lì là.”

14 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gílígálì, kí a lè fi ẹṣẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù múlẹ̀ bí ọba.”

15 Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gílígálì, wọn sí fí Ṣọ́ọ̀lù jọba ní ìwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní ìwájú Olúwa, Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo Ísírẹ́lì ṣe àjọyọ̀ ńlà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31