1 Sámúẹ́lì 13 BMY

Sámúẹ́lì fi Ṣọ́ọ̀lù bú

1 Ṣọ́ọ̀lù sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jọba, ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún méjìlélógójì.

2 Ṣọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì (2000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Míkimásì àti ní ìlú òkè Bẹ́tẹ́lì ẹgbẹ̀rún kan (1000) sì wà lọ́dọ̀ Jónátanì ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.

3 Jónátánì sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì ní Gébà, Fílístínì sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Hébérù gbọ́!”

4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì, Ísírẹ́lì sì di òórùn búburú fún àwọn Fílístínì.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti dara pọ̀ mọ́ Ṣọ́ọ̀lù ní Gílígálì.

5 Àwọn Fílístínì kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Ísírẹ́lì jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́ẹ̀dógún kẹ̀kẹ́, (3000) ẹgbẹ̀ta (6000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Míkímásì ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Bẹti-Áfénì.

6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ.

7 Àwọn Hébérù mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jọ́dánì sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.Ṣọ́ọ̀lù wà ní Gílígálì ṣíbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù.

8 Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Sámúẹ́lì dá; ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn ènìyàn Ṣọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká.

9 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi,” Ṣọ́ọ̀lù sì rú ẹbọ sísun náà.

10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ náà, Sámúẹ́lì sì dé, Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti lọ kí i.

11 Sámúẹ́lì sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Fílístínì sì kó ara wọ́n jọ ní Míkímásì,

12 mo rò pé, ‘Àwọn Fílístínì yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gílígálì nísinsìn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipa láti rú ẹbọ sísun náà.”

13 Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé.

14 Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

15 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì kúrò ní Gílígálì, ó sì gòkè lọ sí Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, Ṣọ́ọ̀lù sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.

Ísírẹ́lì láìní ohun-ìjà.

16 Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, nígbà tí àwọn Fílístínì dó ní Míkímásì.

17 Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Fílístínì ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ófírà ní agbégbé ìlú Ṣúálì.

18 Òmíràn gba ọ̀nà Bẹti-Hórónì, ẹ̀kẹ́ta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Ṣébóímù tí ó kọjú sí ijù.

19 A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí tí àwọn Fílístínì wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Hébérù yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!”

20 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì tọ àwọn Fílístínì lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ̀ wọn.

21 Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdásímẹ́ta ṣékélì, àti ìdásímẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n ọ̀yà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.

22 Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì ni wọ́n ni wọ́n.

23 Àwọn ẹgbẹ́ ogun Fílístínì sì ti jáde lọ sí ìkọjá Míkímásì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31