1 Sámúẹ́lì 7 BMY

1 Nígbà náà àwọn ará Kiriáti-Jéárímù wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Ábínádábù lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásérì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.

Sámúẹ́lì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Fílístínì Ní Mísípà.

2 Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati Jéárímù. Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí Olúwa.

3 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjòjì àti Áṣitarótì kí ẹ sì farayín jìn fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì”

4 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹra fún Báálì àti Áṣitarótì, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.

5 Nígbà náà ni, Sámúẹ́lì wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí Mísípà, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.”

6 Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mísípà, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gba ààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Sámúẹ́lì sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà.

7 Nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé àwọn Ísírẹ́lì ti péjọ ní Mísípà, àwọn aláṣẹ Fílístínì gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Fílístínì.

8 Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì.”

9 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí kè pe Olúwa nítorí ilé Ísírẹ́lì, Olúwa sì dá a lóhùn.

10 Nígbà tí Sámúẹ́lì ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Fílístínì súnmọ́ tòsí láti bá Ísírẹ́lì ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Fílístínì, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

11 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tú jáde láti Mísípà. Wọ́n sì ń lépa àwọn Fílístínì, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Bẹti-Káírì.

12 Sámúẹ́lì mú òkúta kan ó sì fi lé lẹ̀ láàárin Mísípà àti Ṣénì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbẹnésérì, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.”

13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Fílístínì, wọn kò sì wá sí agbégbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́.Ní gbogbo ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Fílístínì.

14 Àwọn ìlú láti Ékírónì dé Gátì tí àwọn Fílístínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti gbà padà fún Ísírẹ́lì, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Fílístínì. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàárin Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.

15 Sámúẹ́lì tẹ̀ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Ísírẹ́lì. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀.

16 Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Bẹ́tẹ́lì dé Gílígálì dé Mísípà, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ibi wọ̀nyí.

17 Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rámà, níbí, ó sì tún ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31