1 Sámúẹ́lì 3 BMY

Olúwa Pe Sámúẹ́lì

1 Sámúẹ́lì ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Élì. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

2 Ní alẹ́ ọjọ́ kan Élì ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáadáa, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìn wá.

3 Nígbà tí iná kò tí ì kú Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ nínú tẹ́ḿpìlì Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà.

4 Nígbà náà ni Olúwa pe Sámúẹ́lì.Sámúẹ́lì sì dáhùn “Èmi nìyí”

5 Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Élì ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”Ṣùgbọ́n Élì wí fún-un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

6 Olúwa sì tún pè é, “Sámúẹ́lì!” Sámúẹ́lì tún dìde ó tọ Élì lọ, ó sì wí pé, “Èmi nì yí, nítorí tí ìwọ pè mí.”“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

7 Ní àkókò yìí Sámúẹ́lì kò tíì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

8 Olúwa pe Sámúẹ́lì ní ìgbà kẹ́tà, Sámúẹ́lì sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì ó sì wí pé, “Èmi nì yí; nítorí tí ìwọ pè mí.”Nígbà náà ni Élì wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà.

9 Nítorí náà Élì sọ fún Sámúẹ́lì, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìrànṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

10 Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì!”Nígbà náà ni Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Má a wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

11 Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Ísírẹ́lì tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro.

12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Élì ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

13 Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.

14 Nítorí náà, mo búra sí ilé Élì, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Élì ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

15 Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Élì.

16 Ṣùgbọ́n Élì pè é, ó sì wí pé, “Sámúẹ́lì, ọmọ mi.”Sámúẹ́lì sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

17 Élì béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Olúwa mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.”

18 Sámúẹ́lì sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Élì wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

19 Olúwa wà pẹ̀lú Sámúẹ́lì bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà.

20 Gbogbo Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíáṣébà mọ̀ pé a ti fa Sámúẹ́lì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa.

21 Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn-án ní Ṣílò, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31