1 Sámúẹ́lì 18 BMY

Ṣọ́ọ̀lù Ń Jowú Dáfídì

1 Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Ṣọ́ọ̀lù sọ, ọkàn Jónátanì di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dáfídì, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.

2 Láti ọjọ́ náà Ṣọ́ọ̀lù pa Dáfídì mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́.

3 Jónátanì bá Dáfídì dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.

4 Jónátanì sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dáfídì pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.

5 Ohunkóhun tí Ṣọ́ọ̀lù bá rán an láti ṣe, Dáfídì máa ṣe ní àṣeyọrí, Ṣọ́ọ̀lù náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrin àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Ṣọ́ọ̀lù lọ́rùn pẹ̀lú.

6 Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti pa Fílístínì, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Ísírẹ́lì wá láti pàdé ọba Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tamborínì àti ohun èlò orin.

7 Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé:“Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀Dáfídì sì pa ẹgbẹgbàárún ní tirẹ̀.”

8 Ṣọ́ọ̀lù sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dáfídì pẹ̀lú ẹgbẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?”

9 Lati ìgbà náà lọ ni Ṣọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlára wo Dáfídì.

10 Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Ṣọ́ọ̀lù, ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dáfídì sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀.

11 Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dáfídì pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dáfídì yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.

12 Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ̀rù Dáfídì nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì, ṣùgbọ́n ó ti fi Ṣọ́ọ̀lù sílẹ̀.

13 Ó sì lé Dáfídì jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dáfídì ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

14 Nínú ohun tí ó bá ṣe, ó ń ní àṣeyọrí ńlá, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.

15 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀.

16 Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà ni wọ́n fẹ́ràn Dáfídì, nítorí ó darí wọn ní ìgbòkègbodò ogun wọn.

17 Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”

18 Ṣùgbọ́n Dáfídì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Ísírẹ́lì, tí èmi yóò di àna ọba?”

19 Nígbà tí àkókò tó fún Mérábù, ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù, láti fi fún Dáfídì, ni a sì fi fún Ádíríélì ara Méhólátì ní aya.

20 Nísinsìn yìí ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì, nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn.

21 Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ tàkúté fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Nísinsìn yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna àn mi.”

22 Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

23 Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dáfídì. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”

24 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sọ fún un ohun tí Dáfídì sọ,

25 Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Sọ fún Dáfídì pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn ún Fílístínì lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀ta rẹ̀.’ ” Èrò Ṣọ́ọ̀lù ni wí pé kí Dáfídì ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.

26 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dáfídì, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá,

27 Dáfídì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Fílístínì. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó baà lè jẹ́ àna ọba. Ṣọ́ọ̀lù sì fi ọmọ obìnrin Míkálì fún un ní aya.

28 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì tí ọmọbìnrin rẹ̀ Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì,

29 Ṣọ́ọ̀lù sì tún wá bẹ̀rù rẹ̀ sí, ó sì jẹ́ ọ̀ta rẹ̀ fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tó kù.

30 Àwọn olórí ogun Fílístínì tún tẹ̀ṣíwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dáfídì ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31