1 Sámúẹ́lì 24 BMY

Dáfídì Gé Etí Aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.

1 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù padà kúrò lẹ́yìn àwọn Fílístínì a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dáfídì ń bẹ́ ni ihà Éńgédì.”

2 Ṣọ́ọ̀lù sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Ísírẹ́lì ó sì lọ láti wá Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lorí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.

3 Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹṣẹ̀ rẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà.

4 Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dáfídì sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.

5 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dáfídì nítorí tí ó gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.

6 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọdọ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi àmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni.”

7 Dáfídì sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.

8 Dáfídì sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Ṣọ́ọ̀lù pé, “Olúwa mi, ọba!” Ṣọ́ọ̀lù sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dáfídì sì dojú rẹ́ bọ ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un.

9 Dáfídì sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èé ha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dáfídì ń wa ẹ̀mí rẹ́’?

10 Wò ó, ojú rẹ́ ríi lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni-àmì-òróró Olúwa ni òun jẹ́.’

11 Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mi mi láti gbà á.

12 Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lara rẹ.

13 Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwá-búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

14 “Nítorí ta ni ọba Ísírẹ́lì fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin?

15 Kí Olúwa ó ṣe onídájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrin èmi àti ìwọ, kí ó sì gbéjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

16 Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dáfídì ọmọ mi?” Ṣọ́ọ̀lù sì gbé ohùn rẹ̀ sòkè, o sunkún.

17 Ó sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ire san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ.

18 Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi èmi mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí.

19 Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọta rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ire san èyí ti ìwọ́ ṣe fún mi lónìí.

20 Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Ísírẹ́lì yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ.

21 Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú ọmọ mi kúrò lẹ́yin mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orukọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”

22 Dáfídì sì búra fún Ṣọ́ọ̀lù. Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31