1 Sámúẹ́lì 14 BMY

Jónátanì Kọlu Àwọn Fílístínì.

1 Ní ọjọ́ kan, Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Fílístínì tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.

2 Ṣọ́ọ̀lù sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gíbéà lábẹ́ igi pòmégánétè èyí tí ó wà ní Mígírónù. Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin (600) sì wà pẹ̀lú rẹ̀,

3 lára wọn ni Áhíjà, tí ó wọ Éfódù. Òun ni ọmọ arákùnrin Íkábódù Áhítúbì, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élì, àlùfáà Olúwa ní Ṣílò kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jónátanì ti lọ.

4 Ní ọ̀nà tí Jónátanì ti ń fẹ́ láti kọjá dé ìlú olódi àwọn Fílístínì, ní bèbè òkúta mímú kan wá, orúkọ èkíní sì ń jẹ́ Bóṣéṣì, orúkọ èkejì sì ń jẹ́ Sénè.

5 Bèbè òkúta kan dúró sí àríwá ní ìhà Míkímásì, èkejì sì wà ní gúsù ní ìhà Gíbéà.

6 Jónátanì sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlu olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípaṣẹ̀ púpọ̀ tàbí nípaṣẹ̀ díẹ̀.”

7 Ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì wí pé, “Ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ, tẹ̀ṣíwájú; Èmi wà pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ.”

8 Jónátanì sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa.

9 Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró síbi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ.

10 Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”

11 Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Hébérù ń fà jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.”

12 Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jónátánì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”Jónátánì sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́.”

13 Jónátánì lo ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Fílístínì sì ṣubú níwájú Jónátánì ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀.

14 Ní ìkọlù èkíní yìí, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbégbé tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sarè ilẹ̀.

15 Nígbà náà ni ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ọmọ ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Àwọn Ogun Fílístínì Sá Àsálà.

16 Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Sàúlù ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì sì rí àwọn ọmọ ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà.

17 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wòó, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.

18 Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Áhíjà pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà náà.

19 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Fílístínì sì ń pọ̀ ṣíwájú sí. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”

20 Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Fílístínì ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkéjì rẹ̀.

21 Àwọn Hébérù tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Fílístínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì.

22 Nígbà tí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Éfúráímù gbọ́ pé àwọn Fílístínì sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná.

23 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Bẹti-Áfénì.

Jónátanì Jẹ Oyin

24 Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀ta mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.

25 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà.

26 Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ ṣíbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré.

27 Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.

28 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”

29 Jónátánì sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdàámú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí.

30 Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀ta wọn lónìí, pípa àwọn Fílístínì ìbá ti pọ̀ tó?”

31 Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa nínú àwọn Fílístínì láti Míkímásì dé Áíjálónì, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà.

32 Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀.

33 Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́sẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹrán tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.”Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá síbi nísinsìn yìí.”

34 Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun tẹ̀jẹ̀.’ ”Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

35 Nígbà náà Ṣọ́ọ̀lù kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

36 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Fílístínì lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má sìṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.”Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.”Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn ín.”

37 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Fílístínì lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Olúwa kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ wá síhìn ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí.

39 Bí Olúwa tí ó gba Ísírẹ́lì là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jónátanì ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

40 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jónátanì ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.”Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.”

41 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jónátanì àti Ṣọ́ọ̀lù nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

42 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ dìbò láàárin èmi àti Jónátanì ọmọ mi.” Ìbò náà sì mú Jónátanì.

43 Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Jónátanì pé, “Sọ nǹkan tí ìwọ ṣe fún mi.”Jónátanì sì sọ fún un pé, “Mo kàn fi orí ọ̀pá mi tọ́ oyin díẹ̀ wò. Nísinsìn yìí ṣé mo ní láti kú?”

44 Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, bí ìwọ kò bá kú.”

45 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jónátanì kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Ísírẹ́lì? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jónátanì sílẹ̀, kò sì kú.

46 Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù sì dẹ́kun lílépa àwọn Fílístínì, àwọn Fílístínì sì padà sí ìlú wọn.

47 Lẹ́yìn ìgbà tí Ṣọ́ọ̀lù ti jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì; Édómù, àti àwọn ọba Ṣọ́bà, àti àwọn Fílístínì. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n.

48 Ó sì jà tagbáratagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Ámálékì, ó sì ń gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n.

Ìdílé Ṣọ́ọ̀lù

49 Àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù sì ni Jónátánì, Ísúì àti Málíkísúà. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Mérábù àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Míkálì.

50 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Áhínóámù ọmọbìnrin Áhímásì. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ábínérì ọmọ Nérì arákùnrin baba Sọ́ọ̀lù.

51 Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ábínérì baba Nérì sì jẹ́ ọmọ Ábíélì.

52 Ní gbogbo ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, ogun náà sì gbóná sí àwọn Fílístínì, níbikíbi tí Ṣọ́ọ̀lù bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31